Lamentations 1:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọ̀tá ti tọwọ́ bọ ilé ìṣúra rẹ̀, wọ́n sì ti kó gbogbo nǹkan iyebíye inú rẹ̀ lọ; ó ń wo àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, tí wọn ń wọ ibi mímọ́ rẹ̀. Àwọn tí ó pàṣẹ pé wọn kò gbọdọ̀ dé àwùjọ àwọn eniyan rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Aninilara ti nà ọwọ rẹ̀ jade sori gbogbo ohun daradara rẹ̀: nitori on ti ri pe awọn orilẹ-ède wọ ibi-mimọ́ rẹ̀, eyiti iwọ paṣẹ pe, nwọn kì o wọ inu ijọ tirẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀tá ti gbọ́wọ́ lé gbogbo ìní rẹ; o rí àwọn ìlú abọ̀rìṣà tí wọ́n wọ ibi mímọ́ rẹ— àwọn tí o ti kọ̀ sílẹ̀ láti wọ ìpéjọpọ̀ rẹ.