Lamentations 1:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ ń kérora bí wọ́n ti ń wá oúnjẹ; wọ́n ń fi ìṣúra wọn ṣe pàṣípààrọ̀ fún oúnjẹ kí wọ́n baà lè lágbára. Jerusalẹmu ń sunkún pé, “Bojúwò mí, OLUWA, nítorí pé mo di ẹni ẹ̀gàn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn enia rẹ̀ kẹdùn, nwọn wá onjẹ; nwọn fi ohun daradara fun onjẹ lati tu ara wọn ninu. Wò o, Oluwa, ki o si rò! nitori emi di ẹni-ẹ̀gan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn rẹ̀ ń kérora bí wọ́n ti ń wá oúnjẹ; wọ́n fi ohun ìní wọn se pàsípààrọ̀ oúńjẹ láti mú wọn wà láàyè. “Wò ó, OLÚWA, kí o sì rò ó, nítorí a kọ̀ mí sílẹ̀.”