Lamentations 1:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ní, “Ṣé ọ̀rọ̀ yìí kò kàn yín ni, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń kọjá lọ? Ẹ̀yin náà ẹ wò ó, kí ẹ ṣe akiyesi rẹ̀, bóyá ìbànújẹ́ kan wà tí ó dàbí èyí tí ó dé bá mi yìí; tí OLUWA mú kí ó dé bá mi, ní ọjọ́ ibinu gbígbóná rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kò ha kàn nyin bi, gbogbo ẹnyin ti nkọja? Wò o, ki ẹ si ri bi ibanujẹ kan ba wà bi ibanujẹ mi, ti a ṣe si mi! eyiti Oluwa fi pọn mi loju li ọjọ ibinu gbigbona rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Kò ha jẹ́ nǹkankan sí i yín? Gbogbo ẹ̀yin tí ń ré kọjá, Ǹjẹ́ ẹnìkan ń jìyà bí èmi ti ń jìyà tí a fi fún mi, ti OLÚWA mú wá fún mi ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ̀.