Lamentations 1:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“OLUWA ti fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn akọni mi mọ́lẹ̀; ó pe ọpọlọpọ eniyan jọ sí mi, ó ní kí wọ́n pa àwọn ọdọmọkunrin mi; OLUWA ti tẹ àwọn ọmọ Juda ní àtẹ̀rẹ́, bí ẹni tẹ èso àjàrà fún ọtí waini.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa ti tẹ̀ gbogbo awọn akọni mi mọlẹ labẹ ẹsẹ li arin mi: On ti pe apejọ sori mi lati tẹ̀ awọn ọdọmọkunrin mi rẹ́: Oluwa ti tẹ ifunti fun wundia, ọmọbinrin Juda.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“OLÚWA kọ àwọn akọni mi sílẹ̀, ó rán àwọn ológun lòdì sí mi kí wọn pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi run. Nínú ìfúntí wáìnì rẹ̀ OLÚWA tẹ́ àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Júdà.