Lamentations 1:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi ni mo ṣe sọkún; tí omijé ń dà lójú mi; olùtùnú jìnnà sí mi, kò sí ẹni tí ó lè dá mi lọ́kàn le. Àwọn ọmọ mi ti di aláìní, nítorí pé àwọn ọ̀tá ti borí wa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi nsọkun nitori nkan wọnyi; oju mi! oju mi ṣàn omi silẹ, nitoripe olutunu ati ẹniti iba mu ọkàn mi sọji jina si mi: awọn ọmọ mi run, nitoripe ọta bori.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ìdí nìyí tí mo fi ń sunkún tí omijé sì ń dà lójú mi, Olùtùnú àti ẹni tí ó le mú ọkàn mi sọjí jìnnà sími, kò sí ẹni tí yóò dá ẹ̀mí mi padà. Àwọn ọmọ mi di aláìní nítorí ọ̀ta ti borí.”