Lamentations 1:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Sioni na ọwọ́ rẹ̀ fún ìrànwọ́, Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́, OLUWA ti pàṣẹ pé, kí àwọn aládùúgbò Jakọbu di ọ̀tá rẹ̀; Jerusalẹmu sì ti di eléèérí láàrin wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sioni nà ọwọ rẹ̀ jade, kò si sí ẹnikan lati tù u ninu: Oluwa ti paṣẹ niti Jakobu pe, ki awọn aninilara rẹ̀ ki o yi i kakiri: Jerusalemu dabi obinrin ẹlẹgbin lãrin wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣíónì na ọwọ́ jáde, ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún un. OLÚWA ti pàṣẹ fún Jákọ́bù pé àwọn ará ilé rẹ̀ di ọ̀ta fún un Jérúsálẹ́mù ti di ohun aláìmọ́ láàrin wọn.