Lamentations 1:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ohun tí ó tọ́ ni OLUWA ṣe, nítorí mo ti ṣe àìgbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ̀; ṣugbọn, ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan, ẹ kíyèsí ìjìyà mi; wọ́n ti kó àwọn ọdọmọbinrin ati ọdọmọkunrin mi lọ sí ìgbèkùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa ṣe olododo; nitoriti emi ti ṣọ̀tẹ si aṣẹ ẹnu rẹ̀: gbọ́, (emi bẹ nyin,) gbogbo orilẹ-ède, ẹ si wò ikãnu mi; awọn wundia mi ati awọn ọdọmọkunrin mi lọ si igbekun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Olóòtítọ́ ni OLÚWA, ṣùgbọ́n mo ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀. Ẹ gbọ́, gbogbo ènìyàn; ẹ wò mí wò ìyà mi. Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi ni a ti kó lọ sí ìgbèékùn.