Lamentations 1:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Mo ké pe àwọn alajọṣepọ mi, ṣugbọn títàn ni wọ́n tàn mí; àwọn alufaa ati àwọn àgbààgbà mi ṣègbé láàrin ìlú, níbi tí wọn ti ń wá oúnjẹ kiri, tí wọn óo jẹ, kí wọn lè lágbára
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi pè awọn olufẹ mi, awọn wọnyi tàn mi jẹ: awọn alufa mi, ati àgbagba mi jọwọ ẹmi wọn lọwọ ni ilu, nigbati nwọn nwá onjẹ wọn lati mu ẹmi wọn sọji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Mo pe àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣùgbọ́n wọ́n tàn mí. Àwọn olórí àlùfáà àti àgbààgbà mi ṣègbé sínú ìlú nígbà tí wọ́n ń wá oúnjẹ tí yóò mú wọn wà láàyè.