Lamentations 1:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Bojúwò mí, OLUWA, nítorí mo wà ninu ìpọ́njú, ọkàn mi ti dàrú, inú mi bàjẹ́, nítorí pé mo ti hùwà ọ̀tẹ̀ lọpọlọpọ. Níta gbangba, ogun ń pa mí lọ́mọ; bákan náà ni ikú ń bẹ ninu ilé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wò o, Oluwa: nitoriti emi wà ninu ipọnju: inu mi nhó; ọkàn mi yipada ninu mi; nitoriti emi ti ṣọ̀tẹ gidigidi: lode, idà sọni di alailọmọ, ni ile, o dabi ikú!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“OLÚWA, wòó, bí mo ti wà nínú ìnira! Tí mo sì ń jẹ̀rora nínú mi, ìdààmú dé bá ọkàn mi nítorí pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi gidigidi. Ní gbangba ni idà ń parun; ikú wà nínú ilé pẹ̀lú.