Lamentations 1:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Gbọ́ bí mo ti ń kérora, kò sí ẹnìkan tí yóo tù mí ninu. Gbogbo àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ nípa ìyọnu mi; inú wọn sì dùn, pé ìwọ ni o kó ìyọnu bá mi. Jẹ́ kí ọjọ́ tí o dá tètè pé, kí àwọn náà lè dàbí mo ti dà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn gbọ́ bi emi ti nkẹdùn to: sibẹ kò si olutunu fun mi: gbogbo awọn ọta mi gbọ́ iyọnu mi; inu wọn dùn nitori iwọ ti ṣe e: iwọ o mu ọjọ na wá ti iwọ ti dá, nwọn o si ri gẹgẹ bi emi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìrora mi, ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún mi. Àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ ìparun mi; wọ́n yọ̀ sí ohun tí o ṣe. Kí o mú ọjọ́ tí o ti kéde, kí wọ́n le dàbí tèmi.