Lamentations 1:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Juda ti lọ sí ìgbèkùn, wọ́n sì ń fi tipátipá mú un sìn. Nisinsinyii, ó ń gbé ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, kò sì ní ibi ìsinmi. Ọwọ́ àwọn tí wọn ń lépa rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ́, ninu ìdààmú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Juda lọ si àjo nitori ipọnju ati isin-ẹrú nla: o joko lãrin awọn orilẹ-ède, on kò ri isimi: gbogbo awọn ti nlepa rẹ̀ ba a ni ibi hiha.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìjìyà àti ìpọ́njú nínú oko ẹrú, Júdà lọ sí àjò Ó tẹ̀dó láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, ṣùgbọ́n kò rí ibi ìsinmi. Àwọn tí ó ń tẹ̀le ká a mọ́ ibi tí kò ti le sá àṣálà.