Lamentations 1:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọ̀nà tó lọ sí Sioni ń ṣe ìdárò, nítorí kò sí ẹni tí ó ń gba ibẹ̀ lọ síbi àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ mọ́. Àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti di ahoro, àwọn alufaa rẹ̀ sì ń kẹ́dùn. Wọ́n ń pọ́n àwọn ọmọbinrin rẹ̀ lójú, òun pàápàá sì ń joró lọpọlọpọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọ̀na Sioni wọnni nṣọ̀fọ, nitori ẹnikan kò wá si ajọ-mimọ́: gbogbo ẹnu-bode rẹ̀ dahoro: awọn alufa rẹ̀ kẹdun, awọn wundia rẹ̀ nkãnu, on si wà ni kikoro ọkàn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ Ṣíónì ń sọ̀fọ̀, nítorí kò sẹ́ni tí ó wá láti jọ́sìn. Ẹnu bodè pátapáta ni ó dahoro, àwọn Olórí àlùfáà ibẹ̀ kérora, àwọn ọ̀dọ́bìnrin rẹ̀ sì ń kẹ́dùn, òun gan-an wà pẹ̀lú ìbànújẹ́ ọkàn.