Lamentations 1:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ ìpọ́njú ati ìbànújẹ́, Jerusalẹmu ranti àwọn nǹkan iyebíye tí ó ní ní ìgbà àtijọ́. Nígbà tí àwọn eniyan rẹ̀ bọ́ sọ́wọ́ ọ̀tá, tí kò sì sí ẹni tí yóo ràn wọ́n lọ́wọ́. Àwọn ọ̀tá bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ ọ́, wọ́n sì ń fi ṣẹ̀sín nítorí ìṣubú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ ipọnju rẹ̀ ati inilara rẹ̀ ni Jerusalemu ranti gbogbo ohun daradara ti o ti ni li ọjọ igbãni, nigbati awọn enia rẹ̀ ṣubu si ọwọ ọta, ẹnikan kò si ràn a lọwọ: awọn aninilara ri i, nwọn si fi iparun rẹ̀ ṣẹsin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ ìpọ́njú àti àrìnká rẹ̀ ni Jérúsálẹ́mù rántí àwọn ohun ìní dáradára rẹ̀ tí ó jẹ́ tirẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́. Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣubú sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá, kò sì sí olùrànlọ́wọ́ fún un. Àwọn ọ̀tá rẹ̀ wò ó wọ́n sì ń fi ìparun rẹ̀ ṣẹlẹ́yà.