Lamentations 1:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jerusalẹmu ti dẹ́ṣẹ̀ burúkú, nítorí náà ó ti di eléèérí. Àwọn tí wọn ń bu ọlá fún un tẹ́lẹ̀ ti ń kẹ́gàn rẹ̀, nítorí pé wọ́n ti rí ìhòòhò rẹ̀. Òun pàápàá ń kérora, ó sì fi ojú pamọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jerusalemu ti da ẹ̀ṣẹ gidigidi, nitorina li o ṣe di ẹni-irira: gbogbo awọn ti mbu ọla fun u kẹgan rẹ̀, nitoripe nwọn ri ihoho rẹ̀: lõtọ on kẹdùn, o si yi ẹ̀hin pada.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jérúsálẹ́mù sì ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ ó sì ti di aláìmọ́. Àwọn tí ó ń tẹríba fún un sì kẹ́gàn rẹ̀, nítorí wọ́n ti rí ìhòòhò rẹ̀; ó kérora fúnra rẹ̀, ó sì lọ kúrò.