Lamentations 1:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìwà èérí rẹ̀ hàn níbi ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, kò sì bìkítà fún ìparun tí ń bọ̀. Nítorí náà ni ìṣubú rẹ̀ fi pọ̀, tí kò sì fi ní olùtùnú. Ó ké pe OLUWA pé kí ó ṣíjú wo ìnira òun, nítorí pé ọ̀tá ti borí rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẽri rẹ̀ wà ni iṣẹti aṣọ rẹ̀; on kò si ranti opin rẹ̀ ikẹhin; nitorina ni o ṣe sọkalẹ ni isọkalẹ iyanu: kò ni olutunu, Oluwa, wò ipọnju mi, nitori ọta ti bori!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìdọ̀tí wà ní etí aṣọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò wo ọjọ́ iwájú rẹ̀, Ìṣubú rẹ̀ ya ni lẹ́nu; olùtùnú kò sì sí fún un. “Wo ìpọ́njú mi, OLÚWA, nítorí àwọn ọ̀ta ti borí.”