Lamentations 2:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí wọ́n ti ń dákú láàrin ìlú, bí ẹni tí a ṣá lọ́gbẹ́, tí wọ́n sì ń kú lọ lẹ́yìn ìyá wọn, wọ́n ń sọkún sí àwọn ìyá wọn pé: “Ebi ń pa wá, òùngbẹ sì ń gbẹ wá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn nsọ fun iya wọn pe, Nibo ni ọka ati ọti-waini gbe wà? nigbati nwọn daku gẹgẹ bi awọn ti a ṣalọgbẹ ni ita ilu na, nigbati ọkàn wọn dà jade li aiya iya wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n wí fún àwọn ìyá wọn, “Níbo ni àkàrà àti wáìnì wà?” Wò ó bí wọ́n ṣe ń kú lọ bí àwọn ọkùnrin tí a ṣe léṣe ní àwọn òpópónà ìlú, bí ayé wọn ṣe ń ṣòfò láti ọwọ́ ìyá wọn.