Lamentations 2:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí ni mo lè sọ nípa rẹ, kí sì ni ǹ bá fi ọ́ wé, Jerusalẹmu? Kí ni mo lè fi wé ọ, kí n lè tù ọ́ ninu, ìwọ Sioni? Nítorí bí omi òkun ni ìparun rẹ gbòòrò; ta ló lè mú ọ pada bọ̀ sípò?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kili ohun ti emi o mu fi jẹri niwaju rẹ? kili ohun ti emi o fi ọ we, iwọ ọmọbinrin Jerusalemu? kili emi o fi ba ọ dọgba, ki emi ba le tù ọ ninu, iwọ wundia ọmọbinrin Sioni? nitoripe ọgbẹ rẹ tobi gẹgẹ bi okun; tali o le wò ọ sàn?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ni mo le sọ fún ọ? Pẹ̀lú u kí ni mo lè fi ọ́ wé, Ìwọ ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù? Kí sì ni mo lè fi ọ́ wé, kí n lè tù ọ́ nínú, Ìwọ wúndíá bìnrin Síónì? Ọgbẹ́ rẹ jìn bí òkun. Ta ni yóò wò ọ́ sàn?