Lamentations 2:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìran èké ati ti ẹ̀tàn ni àwọn wolii rẹ ń rí sí ọ; wọn kò fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ hàn ọ́, kí wọ́n lè dá ire rẹ pada, ṣugbọn wọ́n ń ríran èké ati ìran ẹ̀tàn sí ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn woli rẹ ti riran ohun asan ati wère fun ọ: nwọn kò si ti fi aiṣedede rẹ hàn ọ, lati yi igbekun rẹ pada kuro; ṣugbọn nwọn ti riran ọ̀rọ-wiwo eke fun ọ ati imuniṣina.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìran àwọn wòlíì rẹ jẹ́ kìkì ẹ̀tàn láìní ìwọ̀n; wọn kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn tí yóò mú ìgbèkùn kúrò fún ọ. Àwọn òrìṣà tí wọ́n fún ọ jẹ́ èké àti ìsìnà.