Lamentations 2:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àwọn tí ń rékọjá lọ ń pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí, wọ́n ń pòṣé, wọ́n sì ń mi orí wọn sí ọ, Jerusalẹmu. Wọ́n ń sọ pé: “Ṣé ìlú yìí ni à ń pè ní ìlú tí ó lẹ́wà jùlọ, tí ó jẹ́ ayọ̀ gbogbo ayé?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn ti nkọja patẹwọ le ọ; nwọn nṣẹsin, nwọn si nmì ori wọn si ọmọbinrin Jerusalemu; pe, Ilu na ha li eyi, ti a npè ni: Pipe-ẹwà, Ayọ̀ gbogbo ilẹ aiye!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn tí ó gba ọ̀nà ọ̀dọ̀ rẹ pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí; wọ́n kẹ́gàn wọ́n ju orí wọn sí ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù: “Èyí ha ni ìlú tí à ń pè ní àṣepé ẹwà, ìdùnnú gbogbo ayé?”