Lamentations 2:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ ń fi ọ́ ṣẹ̀sín, wọ́n ń pòṣé, wọ́n ń fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà. Wọ́n ń wí pé: “A ti pa á run! Ọjọ́ tí a tí ń retí nìyí; ọwọ́ wa ti tẹ Jerusalẹmu wàyí! A ti rí ohun tí à ń wá!”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn ọta rẹ ya ẹnu wọn si ọ; nwọn nṣe ṣiọ! nwọn si npa ehin keke, nwọn wipe: Awa ti gbe e mì; dajudaju eyi li ọjọ na ti awa ti nwọ̀na fun; ọwọ ti tẹ̀ ẹ, awa ti ri i!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ la ẹnu wọn gbòòrò sí ọ; wọ́n kẹ́gàn, wọ́n sì payín keke wọ́n wí pé, “A ti gbé e mì tán. Èyí ni ọjọ́ tí a ti ń retí; tí a sì wá láti rí.”