Lamentations 2:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wò ó! OLUWA, ṣe akiyesi ohun tí ń ṣẹlẹ̀! Wo àwọn tí ò ń ṣe irú èyí sí! Ṣé ó yẹ kí àwọn obinrin máa jẹ ọmọ wọn? Ọmọ ọwọ́ tí wọn ń tọ́jú! Ṣé ó yẹ kí á pa alufaa ati wolii, ní ibi mímọ́ OLUWA?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wò o, Oluwa, ki o rò, fun tani iwọ ti ṣe eyi? Awọn obinrin ha le ma jẹ eso-inu wọn, awọn ọmọ-ọwọ ti nwọn npọ̀n? a ha le ma pa alufa ati woli ni ibi mimọ́ Oluwa?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Wòó, OLÚWA, kí o sì rò ó: Ta ni ìwọ ti fìyà jẹ bí èyí Ǹjẹ́ àwọn obìnrin yóò ha jẹ ọmọ wọn, àwọn ọmọ tí wọn ń se ìtọ́jú fún? Ǹjẹ́ kí a pa olórí àlùfáà àti àwọn wòlíì ní ibi mímọ́ OLÚWA?