Lamentations 2:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àtàwọn ọ̀dọ́, àtàwọn arúgbó wọ́n kú kalẹ̀ lọ lójú pópó, àtàwọn ọdọmọbinrin, àtàwọn ọdọmọkunrin mi, gbogbo wọn ni idà ti pa. Ní ọjọ́ ibinu rẹ ni o pa wọ́n, o pa wọ́n ní ìpakúpa láìṣàánú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ewe ati arugbo dubulẹ ni ita wọnni: awọn wundia mi ati awọn ọdọmọkunrin mi ṣubu nipa idà: iwọ ti pa li ọjọ ibinu rẹ; iwọ ti pa, iwọ kò si dasi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọmọdé àti àgbà ń sùn papọ̀ sínú eruku àwọn òpópó; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi ti ṣègbé nípa idà. Ìwọ pa wọ́n run ní ọjọ́ ìbínú rẹ; Ìwọ pa wọ́n láìní àánú.