Lamentations 2:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ti fi ibinu gbígbóná rẹ̀, pa àwọn alágbára Israẹli; ó kọ̀, kò ràn wọ́n lọ́wọ́, nígbà tí àwọn ọ̀tá dojú kọ wọ́n. Ó jó àwọn ọmọ Jakọbu bí iná, ó sì pa gbogbo ohun tí wọn ní run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O ti ke gbogbo iwo Israeli kuro ninu ibinu gbigbona rẹ̀: o ti fà ọwọ ọtun rẹ̀ sẹhin niwaju ọta, o si jo gẹgẹ bi ọwọ iná ninu Jakobu ti o jẹrun yikakiri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó ké gbogbo ìwo Ísírẹ́lì. Ó ti mú ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kúrò nígbà tí àwọn ọ̀tá dé. Ó run ní Jákọ́bù bí ọ̀wọ́ iná ní àgọ́ àwọn ọmọbìnrin Síónì.