Lamentations 2:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ṣe bí ọ̀tá, ó ti pa Israẹli run. Ó ti pa gbogbo ààfin rẹ̀ run, ó sọ àwọn ibi ààbò rẹ̀ di àlàpà ó sì sọ ọ̀fọ̀ ati ẹkún Juda di pupọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa jẹ gẹgẹ bi ọta: o ti gbe Israeli mì, o ti gbe gbogbo ãfin rẹ̀ mì: o ti pa ilu olodi rẹ̀ run o si ti fi ibanujẹ lori ibanujẹ fun ọmọbinrin Juda.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA dà bí ọ̀tá; ó gbé Ísírẹ́lì mì. Ó ti gbé gbogbo ààfin rẹ̀ mì ó pa ibi gíga rẹ̀ run. Ó sọ ìmí ẹ̀dùn àti ìbànújẹ́ di púpọ̀ fún àwọn ọmọbìnrin Júdà.