Lamentations 2:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó wó àgọ́ rẹ̀ lulẹ̀, bí ìgbà tí eniyan wó ahéré oko. Ó pa gbogbo ibi tí wọ́n ti ń ṣe àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ run. OLUWA ti fi òpin sí àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀, ati ọjọ́ ìsinmi ní Sioni. Ó sì ti fi ibinu gbígbóná rẹ̀, kọ ọba ati alufaa sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ti wó ọgba rẹ̀ lulẹ, gẹgẹ bi àgbala: o ti pa ibi apejọ rẹ̀ run: Oluwa ti mu ki a gbagbe ajọ-mimọ́ ati ọjọ isimi ni Sioni, o ti fi ẹ̀gan kọ̀ ọba ati alufa silẹ ninu ikannu ibinu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó mú ìparun bá ibimímọ́, ó pa ibi ìpàdé rẹ̀ run. OLÚWA ti mú Síónì gbàgbé ọjọ́ àṣè àti ọ̀ṣẹ̀ tí ó yàn; nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó run ọba àti olórí àlùfáà.