Lamentations 2:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA kò bìkítà fún pẹpẹ rẹ̀ mọ́, ó sì ti kọ ibi mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Ó ti fi odi ààfin rẹ̀ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́; wọ́n pariwo ńlá ninu ilé OLUWA gẹ́gẹ́ bíi ti ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa ti ṣá pẹpẹ rẹ̀ tì, o ti korira ibi-mimọ́ rẹ̀, o ti fi ogiri ãfin rẹ̀ le ọwọ ọta; nwọn ti pa ariwo ninu ile Oluwa, gẹgẹ bi li ọjọ ajọ-mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA ti kọ̀ pẹpẹ rẹ̀ sílẹ̀ ó sì ti kọ̀ ibi mímọ́ rẹ̀. Ó sì fi lé ọ̀ta lọ́wọ́ àwọn odi ààfin rẹ̀; wọ́n sì kígbe ní ilé OLÚWA gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìpèjẹ tí a yàn.