Lamentations 2:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ti pinnu láti wó odi Sioni lulẹ̀. Ó fi okùn ìwọ̀n wọ̀n ọ́n, kò sì rowọ́ láti parun. Ó jẹ́ kí ilé ìṣọ́ ati odi ìlú wó lulẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́, wọ́n sì di àlàpà papọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa ti rò lati pa odi ọmọbinrin Sioni run: o ti nà okùn ìwọn jade, on kò ti ifa ọwọ rẹ̀ sẹhin kuro ninu ipanirun: bẹ̃ni o ṣe ki ile-iṣọ rẹ̀ ati odi rẹ̀ ki o ṣọ̀fọ; nwọn jumọ rẹ̀ silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA pinnu láti fa ògiri tí ó yí ọmọbìnrin Síónì ya. Ó gbé wọn sórí òṣùnwọ̀n, kò sì fa ọwọ́ rẹ̀ padà kúrò nínú ìparun wọn. Ó mú kí ilé-ìsọ́ àti odi rẹ̀ sọ̀fọ̀ wọ́n ṣòfò papọ̀.