Lamentations 4:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn eniyan ń kígbe lé wọn lórí pé; “Ẹ máa lọ! Ẹ̀yin aláìmọ́! Ẹ máa kóra yín lọ! Ẹ má fi ọwọ́ kan nǹkankan!” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe di ìsáǹsá ati alárìnkiri, nítorí àwọn eniyan ń wí láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè pé, “Àwọn wọnyi kò gbọdọ̀ bá wa gbé pọ̀ mọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn nkigbe si wọn pe, ẹ lọ! alaimọ́ ni! ẹ lọ! ẹ lọ! ẹ máṣe fi ọwọ kan a! nigbati nwọn salọ, nwọn si rìn kiri pẹlu: nwọn nwi lãrin awọn orilẹ-ède pe, awọn kì o ṣatipo nibẹ mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Lọ kúrò! Ẹ̀yin di aláìmọ́!” ni àwọn ènìyàn ń kígbe sí wọn. “Ẹlọ! Ẹlọ! Ẹ má se fọwọ́ kàn wá!” Àwọn ènìyàn láàrin orílẹ̀ èdè wí pé, “Wọn kì yóò tẹ̀dó síbí mọ́.”