Lamentations 4:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ máa yọ̀, kí inú yín sì máa dùn, ẹ̀yin ará Edomu, tí ń gbé ilẹ̀ Usi. Ṣugbọn ife náà yóo kọjá lọ́dọ̀ yín, ẹ óo mu ún ní àmuyó, ẹ óo sì tú ara yín síhòòhò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yọ̀, ki inu rẹ si dùn, iwọ ọmọbinrin Edomu, ti ngbe inu ilẹ Usi; sibẹ ago na yio kọja sọdọ rẹ pẹlu: iwọ o si yo bi ọ̀muti, a o si tu ọ ni ihoho.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ yọ̀ kí inú yín sì dùn, ẹ̀yin ọmọbìnrin Édómù, ẹ̀yin tó ń gbé ní ilẹ̀ Húsì. Ṣùgbọ́n, a ó gbé aago náà kọjá sọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú; ìwọ yóò yó bí ọ̀mùtí, ìwọ yóò sì rìn ní ìhòòhò.