Lamentations 4:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn olórí wọn kò ní àléébù kankan, Ọwọ́ wọn mọ́, inú wọn funfun nini, wọ́n dára ju egbin lọ, ẹwà wọn sì dàbí ẹwà iyùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn Nasire rẹ̀ mọ́ jù ẹ̀gbọn-owu, nwọn funfun jù wàra; irisi wọn pọn jù iyùn, apẹrẹ wọn dabi okuta Safire:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọmọ ọba ọkùnrin wọn mọ́ ju òjò dídì, wọ́n sì funfun ju wàrà lọ lára, wọ́n ni ìtọ́jú bí iyùn pupa, ìrísí wọn dàbí sáfírè.