Leviticus 1:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn kí ó fi omi fọ nǹkan inú rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀, kí alufaa fi gbogbo rẹ̀ rúbọ, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ náà. Ẹbọ sísun ni; ẹbọ tí a fi iná sun, tí ó ní òórùn dídùn, tí inú OLUWA dùn sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ki o ṣìn ifun ati itan rẹ̀ ninu omi: ki alufa na ki o si mú gbogbo rẹ̀ wá, ki o si sun u lori pẹpẹ: ẹbọ sisun ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ó fi omi san nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì gbé gbogbo rẹ̀ wá láti sun lórí pẹpẹ. Ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun tí a fi iná se, àní òórùn dídùn sí OLÚWA