Leviticus 1:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí ó fa apá rẹ̀ mejeeji ya, ṣugbọn kí ó má fà wọ́n já. Lẹ́yìn náà kí alufaa sun ún lórí igi tí ó wà ninu iná lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun ni, ẹbọ olóòórùn dídùn tí a fi iná sun sí OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si là a ti on ti iyẹ́-apa rẹ̀, ṣugbọn ki yio pín i ni meji jalẹ: ki alufa ki o si sun u lori pẹpẹ na, lori igi na ti mbẹ lori iná: ẹbọ sisun ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ó gbá apá rẹ̀ méjèèjì mú, kí ó fà á ya, ṣùgbọ́n kí ó má yaá tan pátapáta. Lẹ́yìn náà ni àlùfáà yóò sun ún lórí igi tí ó ń jó lórí pẹpẹ, ọrẹ ẹbọ sísun ni ọrẹ tí a fi iná se, àní òórùn dídùn sí OLÚWA.