Leviticus 1:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn ẹni tí ó wá rúbọ yóo fi omi fọ àwọn nǹkan inú ẹran náà ati ẹsẹ̀ rẹ̀, alufaa yóo sì sun gbogbo rẹ̀ níná lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun, ẹbọ tí a fi iná sun, tí ó jẹ́ ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ifun rẹ̀, ati itan rẹ̀ ni ki o ṣàn ninu omi: ki alufa ki o si sun gbogbo rẹ̀ lori pẹpẹ na lati ṣe ẹbọ sisun, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ó fi omi ṣàn nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ, ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí OLÚWA.