Leviticus 10:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Aaroni meji kan, ọkunrin, tí wọn ń jẹ́ Nadabu ati Abihu, mú àwo turari wọn, olukuluku fọn ẹ̀yinná sinu tirẹ̀, wọ́n da turari lé e lórí, wọ́n sì fi rúbọ níwájú OLUWA, ṣugbọn iná yìí kì í ṣe irú iná mímọ́ tí OLUWA pa láṣẹ fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
ATI Nadabu ati Abihu, awọn ọmọ Aaroni, olukuluku nwọn mú awo-turari rẹ̀, nwọn si fi iná sinu wọn, nwọn si fi turari sori wọn, nwọn si mú ajeji iná wá siwaju OLUWA, ti on kò fi aṣẹ fun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nádábù àti Ábíhù tí í ṣe ọmọ Árónì sì mú àwo tùràrí kọ̀ọ̀kan, wọ́n fi iná àti tùràrí sínú rẹ̀, wọ́n sì rú iná àìmọ́ níwájú OLÚWA, èyí tó lòdì sí àṣẹ OLÚWA.