Leviticus 10:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mose sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji tí wọ́n ṣẹ́kù, Eleasari ati Itamari, ó ní, “Ẹ gbé ohun ìrúbọ tí ó kù ninu ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi iná sun sí OLUWA, kí ẹ sì jẹ ẹ́ lẹ́bàá pẹpẹ, láì fi ìwúkàrà sí i, nítorí pé mímọ́ jùlọ ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si wi fun Aaroni, ati fun Eleasari ati fun Itamari, awọn ọmọ rẹ̀ ti o kù pe, Ẹ mú ẹbọ ohunjijẹ ti o kù ninu ẹbọ OLUWA, ti a fi iná ṣe, ki ẹ si jẹ ẹ lainí iwukàra lẹba pẹpẹ: nitoripe mimọ́ julọ ni:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè sì sọ fún Árónì, Élíásárì àti Ítamárì àwọn ọmọ rẹ̀ yóòkù pé “Ẹ mú ẹbọ ohun jíjẹ tó sẹ́kù láti inú ẹbọ àfinásun sí OLÚWA, kí ẹ jẹ ẹ́ láì ní ìwúkàrà nínú, lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ nítorí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.