Leviticus 10:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n bá mú ọ̀rá ẹran wá fún ẹbọ sísun, tí wọ́n mú itan ẹran tí wọ́n fi rúbọ, ati igẹ̀ àyà rẹ̀ fún ẹbọ fífì níwájú OLUWA, yóo máa jẹ́ tìrẹ, ati ti àwọn ọmọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìpín yín títí ayé, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Itan agbesọsoke ati igẹ̀ fifì ni ki nwọn ki o ma múwa pẹlu ẹbọ ti a fi iná ṣe ti ọrá, lati fì i fun ẹbọ fifì niwaju OLUWA: yio si ma jẹ́ tirẹ, ati ti awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ, nipa ìlana titilai; bi OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Itan tí wọ́n mú wá àti igẹ̀ ẹran tí ẹ fì ni ẹ gbọdọ̀ mú wá pẹ̀lú ọ̀rá ẹbọ tí a finá sun láti le fí wọ́n níwájú OLÚWA bí ẹbọ fífì. Èyí yóò sì jẹ́ ìpín tìrẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ nígbà gbogbo bí OLÚWA ṣe pa á láṣẹ.”