Leviticus 10:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Kí ló dé tí ẹ kò fi jẹ ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ní ibi mímọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé, ohun tí ó mọ́ jùlọ ni, tí ó sì jẹ́ pé ẹ̀yin ni OLUWA ti fún, kí ẹ lè máa ru ẹ̀ṣẹ̀ ìjọ eniyan yìí, kí ẹ sì máa ṣe ètùtù fún wọn níwájú OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori kini ẹnyin kò ṣe jẹ ẹbọ èṣẹ na ni ibi mimọ́, nitoripe mimọ́ julọ ni, a si ti fi fun nyin lati rù ẹ̀ṣẹ ijọ enia, lati ṣètutu fun wọn niwaju OLUWA?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èéṣe tí ẹ kò jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ní agbégbé ibi mímọ́? Ó jẹ́ mímọ́ jùlọ, a fi fún yín láti lè mú ẹ̀ṣẹ̀ ìjọ ènìyàn kúrò nípa fífi ṣe ètùtù fún wọn níwájú OLÚWA.