Leviticus 10:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Aaroni dá Mose lóhùn pé, “Wò ó! Lónìí ni wọ́n rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ sísun wọn sí OLUWA, sibẹsibẹ irú nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ sí mi. Bí ó bá jẹ́ pé mo ti jẹ ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ lónìí ni, ǹjẹ́ ẹbọ náà lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú OLUWA?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Aaroni si wi fun Mose pe, Kiyesi i, li oni ni nwọn ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ wọn ati ẹbọ sisun wọn niwaju OLUWA; irú nkan wọnyi li o si ṣubulù mi: emi iba si ti jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ li oni, o ha le dara li oju OLUWA?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Árónì sì dá Mósè lóhùn pé, “Lónìí tí wọ́n rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ sísun wọn níwájú OLÚWA ni irú èyí tún sẹlẹ̀ sí mi. Ǹjẹ́ inú OLÚWA yóò wá dùn bí mo bá jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lónìí?”