Leviticus 10:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mose bá pe Aaroni, ó wí fún un pé, “Ohun tí OLUWA wí nìyí, ‘N óo fi ara mi hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́ láàrin àwọn tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ mi, n óo sì gba ògo níwájú gbogbo àwọn eniyan’ ” Aaroni dákẹ́, kò sọ̀rọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Mose wi fun Aaroni pe, Eyiyi li OLUWA wipe, A o yà mi simimọ́ ninu awọn ti nsunmọ mi, ati niwaju awọn enia gbogbo li a o yìn mi li ogo. Aaroni si dakẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè sì sọ fún Árónì pé, “Ohun tí OLÚWA ń sọ nípa rẹ̀ nìyìí nígbà tó wí pé” “ ‘Ní àárin àwọn tó súnmọ́ mi, Èmi yóò fí ara mi hàn ní mímọ́ ojú gbogbo ènìyàn Ní a ó ti bu ọlá fún mi’ ” Árónì sì dákẹ́.