Leviticus 10:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose sọ fún Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ meji, Eleasari ati Itamari pé, “Ẹ má ṣe fi irun yín sílẹ̀ játijàti, ẹ má sì ṣe fa aṣọ yín ya (láti fihàn pé ẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀), kí ẹ má baà kú, kí ibinu OLUWA má baà wá sórí gbogbo eniyan. Ṣugbọn gbogbo ilé Israẹli, àwọn eniyan yín, lè ṣọ̀fọ̀ iná tí OLUWA fi jó yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si wi fun Aaroni, ati fun Eleasari ati fun Itamari, awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ máṣe ṣi ibori nyin, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe fà aṣọ nyin ya; ki ẹnyin ki o má ba kú, ati ki ibinu ki o má ba wá sori gbogbo ijọ: ṣugbọn ki awọn arakunrin nyin, gbogbo ile Israeli ki o sọkun ijóna ti OLUWA ṣe yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóòkù, Élíásárì àti Ítamárì pé, “ẹ má ṣe sọ̀fọ̀ nípa ṣíṣe aláìtọ́jú irun yín tàbí kí ẹ sí orí yín sílẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ ya aṣọ, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kùú, OLÚWA yóò sì bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn ẹbí yín, àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì le è ṣọ̀fọ̀ lórí àwọn tí OLÚWA fi iná parun.