Leviticus 10:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ kò sì gbọdọ̀ jáde kúrò ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, kí ẹ má baà kú, nítorí pé òróró ìyàsímímọ́ OLUWA wà lórí yín.” Wọ́n sì ṣe bí Mose ti wí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹnyin ki o má si ṣe jade kuro lati ibi ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ki ẹnyin ki o má ba kú: nitoripe oróro itasori OLUWA mbẹ lara nyin. Nwọn si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ má ṣe kúrò ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, bí ẹ bá kúrò níbẹ̀, ẹ ó kùú, nítorí pé òróró ìtasórí OLÚWA wà lórí yín” Wọ́n sì ṣe bí Mósè ti wí.