Leviticus 11:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ohunkohun tí ó ń gbé inú òkun, tabi inú odò, ninu gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè tí wọn ń káàkiri inú omi, èyíkéyìí tí kò bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́, ohun ìríra ni fun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati gbogbo eyiti kò ní lẹbẹ ati ipẹ́ li okun, ati li odò, ninu gbogbo ohun ti nrá ninu omi, ati ninu ohun alãye kan ti mbẹ ninu omi, irira ni nwọn o jasi fun nyin,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nínú gbogbo ẹ̀dá tí ń gbé inú òkun àti nínú odò tí kò ní lẹbẹ àti ìpẹ́, yálà nínú gbogbo àwọn tí ń rákò tàbí láàrin gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè yòókù tí ń gbé inú omi àwọn ni kí ẹ kórìíra.