Leviticus 11:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sibẹsibẹ ninu àwọn kòkòrò tí wọn ní ìyẹ́, tí wọn ń fi ẹsẹ̀ mẹrẹẹrin rìn, ẹ lè jẹ àwọn tí wọn bá ní tete tí wọ́n fi ń ta káàkiri lórí ilẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn wọnyi ni ki ẹnyin ki o ma jẹ ninu gbogbo ohun ti nfò, ti nrakò, ti nfi gbogbo mẹrẹrin rìn, ti o ní tete lori ẹsẹ̀ wọn, lati ma fi ta lori ilẹ;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
irú àwọn kòkòrò oníyẹ́ tí wọn sì ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn tí ẹ le Jẹ nìyí: Àwọn kòkòrò tí wọ́n ní ìsẹ́po ẹsẹ̀ láti máa fi fò lórí ilẹ̀.