Leviticus 11:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo ẹranko tí pátákò ẹsẹ̀ wọn bá là, ṣugbọn tí ẹsẹ̀ wọn kò là, tí wọn kì í sì í jẹ àpọ̀jẹ, aláìmọ́ ni wọ́n; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kàn wọ́n di aláìmọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹranko gbogbo ti o yà bàta-ẹsẹ̀, ti kò si là ẹsẹ̀, tabi ti kò si jẹ apọjẹ, ki o jẹ́ alaimọ́ fun nyin: gbogbo ẹniti o ba farakàn wọn ki o jẹ́ alaimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Àwọn ẹranko tí pátakò wọn kò là tan tàbí tí wọn kò jẹ àpọ̀jẹ jẹ́ àìmọ́ fún yín. Ẹni tí ó bá fọwọ́ kan òkú èyíkéyí nínú wọn yóò jẹ́ aláìmọ́.