Leviticus 11:34 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ohunkohun tí ó bá jẹ́ jíjẹ tí ó bá wà ninu ìkòkò amọ̀ yìí, tabi tí omi inú rẹ̀ bá ta sí lára, di aláìmọ́, ohunkohun tí ó bá jẹ́ mímu, tí ó wà ninu rẹ̀ náà di aláìmọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ninu onjẹ gbogbo ti a o ba jẹ, ti irú omi nì ba dà si, yio di alaimọ́: ati ohun mimu gbogbo ti a o ba mu ninu irú ohunèlo na yio di alaimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí omi inú ìkòkò náà bá dà sórí èyíkeyí nínú oúnjẹ tí ẹ̀ ń jẹ oúnjẹ náà di aláìmọ́. Gbogbo ohun mímu tí a lè mú jáde láti inú rẹ̀ di àìmọ́.