Leviticus 11:43 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ sọ ara yín di ìríra; ẹ kò gbọdọ̀ kó ẹ̀gbin bá ara yín, kí ẹ má baà di aláìmọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin kò gbọdọ fi ohun kan ti nrakò, sọ ara nyin di irira, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fi wọn sọ ara nyin di alaimọ́ ti ẹnyin o fi ti ipa wọn di elẽri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ má ṣe sọ ara yín di aláìmọ́ nípa èyíkéyí nínú àwọn ohun tí Ọlọ́run dá wọ̀nyí. Ẹ má ṣe sọ ara yín dí àìmọ́ yálà láti ara wọn, tàbí nípaṣẹ̀ wọn.