Leviticus 11:45 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí èmi ni OLUWA tí ó ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá, láti jẹ́ Ọlọrun yín; nítorí náà, ẹ níláti jẹ́ mímọ́, nítorí pé, mímọ́ ni èmi Ọlọrun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe Emi li OLUWA ti o mú nyin gòke ti ilẹ Egipti wá, lati ma ṣe Ọlọrun nyin: nitorina ki ẹnyin ki o jẹ́ mimọ́, nitoripe mimọ́ li Emi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi ni OLÚWA tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín torí náà, ẹ jẹ́ mímọ́ torí pé mímọ́ ni èmi.