Leviticus 12:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Bí obinrin kan bá lóyún tí ó sì bí ọmọkunrin, ó di aláìmọ́ fún ọjọ́ meje, gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ aláìmọ́ nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi obinrin kan ba lóyun, ti o si bi ọmọkunrin, nigbana ni ki o jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje; gẹgẹ bi ọjọ́ ìyasọtọ fun ailera rẹ̀ ni ki o jẹ́ alaimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé: ‘Obìnrin tí ó bá lóyún tí ó sì bí ọmọkùnrin, yóò wà láìmọ́ fún ọjọ́ méje bí ìgbà tí ó wà ní ipò àìmọ́ lákókò nǹkan oṣù rẹ̀.