Leviticus 12:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé obinrin ni ó bí, ọ̀sẹ̀ meji ni yóo fi wà ní ipò àìmọ́ bí ó ti jẹ́ aláìmọ́ nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀; yóo sì wà ninu ẹ̀jẹ̀ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ fún ọjọ́ mẹrindinlaadọrin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi o ba bi ọmọbinrin, nigbana ni ki o jẹ́ alaimọ́ li ọsẹ̀ meji, bi ti inu ìyasọtọ rẹ̀: ki o si wà ninu ẹ̀jẹ ìwẹnumọ́ rẹ̀ li ọgọta ọjọ́ o le mẹfa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó bá ṣe obìnrin ni ó bí, fún ọ̀sẹ̀ méjì ni obìnrin náà yóò fi wà ní ipò àìmọ́, gẹ́gẹ́ bí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀. Ó sì gbọdọ̀ dúró ní ọjọ́ mẹ́rìndínláàdọ́rin (66) láti di mímọ́ kúrò nínú ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.