Leviticus 12:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Alufaa yóo sì fi rúbọ níwájú OLUWA, yóo ṣe ètùtù fún un; nígbà náà ni yóo di mímọ́ kúrò ninu ìṣàn ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Òfin yìí wà fún obinrin tí ó bá bímọ, kì báà jẹ́ ọmọkunrin ni ó bí tabi ọmọbinrin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti yio ru u niwaju OLUWA, ti yio si ṣètutu fun u; on o si di mimọ́ kuro ninu isun ẹ̀jẹ rẹ̀. Eyi li ofin fun ẹniti o bi ọmọkunrin tabi ọmọbinrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó gbọdọ̀ fi wọ́n rú ẹbọ níwájú OLÚWA láti ṣe ètùtù fún obìnrin náà lẹ́yìn náà ni yóò di mímọ́ kúrò nínú ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. “ ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn ìlànà fún obìnrin tí ó bá bí ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin.